BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Àjọ CAN kéde ọjọ́ òní gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ 'Àìkú Dúdú' láti dárò àwọn ọmọ Naijiria tó ń jìyà ètò ààbò tó mẹ́hẹ
CAN kede ọrọ naa ninu iṣẹ ti Aarẹ wọn, Archbishop Daniel Okoh, ran si gbogbo Kristẹni lonii ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa ọdun 2026.
A máa tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn tí yóò parí ogun Iran lọ́jọ́ Àìkú – Donald Trump
Amọ bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Trump kede awọn ọrọ yii, Iran ko fi gbogbo ara gba asiko ti aarẹ America naa n dá.
Ìtàn Mánigbàgbé: Ìdí tí Ọba alayé nílẹ̀ Yorùbá kìí ṣe dúró níbi tí wọn ti ń pa èèyàn tàbí fojú rí òkú
BBC News Yorùbá wọnú ìtàn lọ nípa ìdí tí Ọba alayé nílẹ̀ Yorùbá kìí ṣe dúró níbi tí wọn ti ń pa èèyàn tàbí fojú rí òkú.
Fídíò, Ademola Adeleke àti APC sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ara wọn lẹ́yìn ìjà òṣèlú tó wáyé l'Osun, Duration 5,47
Adeleke sọ pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ ọhun ko ba oun ṣiṣẹ pọ lati yanju rogbodiyan oṣelu to n waye nipinlẹ naa.
Agbébọn kọlu Owo ní ìpínlẹ̀ Ondo, jí baálẹ̀ gbé lọ ní ààfin
Awọn olugbe ilu naa ṣalaye pe awọn agbebọn mẹfa lo wọ aafin naa, ti wọn si sọsẹ yi lai si ẹni to yẹ wọn lọwọ wo.
Fídíò, Kola Oyewo: Ó ti tó ọdún méje ti Kola Oyewo ti ń ṣàìsàn kó tó jáde láyé - Ẹbí, Duration 3,36
Ọgbẹni Adewale Oyewọ to jẹ ọkan lara ọmọ oloogbe Oyewọ ṣalaye pe o ti ṣe diẹ ti aisan ti n ṣe agba oye Kọla Oyewọ bi o tilẹ jẹ wi pe ko le to eyi to fa iku rẹ yii.
Switzerland fẹ́ ṣòfin tí kò ní jẹ́ kí gbogbo èèyàn orílẹ̀èdè náà kọjá mílíọ́nù mẹ́wàá
Njẹ o ṣeeṣe ki orilẹede kan ma jẹ ki iye eeyan to wa nilẹ rẹ kọja iye ti wọn n fẹ? Ibeere ti orilẹede Switzerland yoo maa dahun lonii ọjọ Aiku ree nibi ipade apero kan.
Wo ìdílé mẹ́wàá tí wọ́n lówó jùlọ káàkiri àgbáyé
Lara awọn nnkan ti wọn ti ṣe to sọ wọn di ọlọrọ ni ile tabi ilẹ tita, aṣọ tita, ounjẹ tita ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Makinde sọ̀rọ̀ lórí ibi táwọn agbébọn kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso pamọ́ sí
Gomina ipinlẹ Oyo sọ ninu atẹjade kan to fi sita fawọn akọroyin pe ninu igbo ijọba Old Oyo National Park lawọn ajinigbe naa wa pẹlu awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso.
Ọ̀gágun fẹ̀yìntì Rabe Abubakar táwọn agbébọn jí gbé pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ ti kú sí àkàtà àwọn jàndùkú ajínigbé
Adari eto iroyin fun ileeṣẹ ologun Naijiria, Maj Gen Samaila Uba, lo fi idi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade ti o fi sita lonii ọjọ Abamẹta ọjọ kẹtala oṣu Kẹfa yii.
Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Kola Oyewo, àgbà òṣèré tíátà Yoruba tó jáde láyé
Àwọn gbajúmọ̀ òṣèré bíi Kunle Afod ati Yomi Ọlọrunlaiye ni wọ́n ti ń daro ipapoda àgbà òṣèré náà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ló ti rẹ̀ sára àmọ́ inú wa dùn pé a gbòmìnira – Àwọn tó gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ Boko Haram
Ọpọ obinrin ati awọn ọmọde ni wọn pe awọn ti wọn ni Boko Haram tu silẹ naa.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Fídíò, Ìdí mẹ́rin tí nǹkan ọkùnrin ṣe máa ń nàró ní àárọ̀ tí wọn bá jí, Duration 1,13
Nínú Fídíò yìí, BBC News Yorùbá ṣe ìwádìí nípa ídí tí nǹkan ọkùnrin ṣe máa ń nàró ní àárọ̀ tí wọn bá jí àti ohun tó ń fà á.
Àwọn agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ nígboro South Africa, èèyàn méjìlá kú, mẹ́sàn-án farapa
Gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe fi han, orilẹede South Africa wa lara awọn ilu ti wọn ti n pa eeyan ju lagbaaye.
Ẹgbẹ́ City Boys tó ń ṣàtìlẹyìn fún Tinubu l‘Oyo ṣàbẹ̀wó sí Esinele, gbé ohun èlò ìwòsàn kalẹ̀, àmọ́ ẹbí Tíṣà tí agbébọn pa kọ àpò ìrẹsì àti owó Ìyálọ́jà, tíí ṣe ọmọ ààrẹ
Nigba to n sọrọ lasiko abẹwo ọhun, Onireti fi ireti han pe wọn maa ṣawari awọn akẹkọọ atawọn olukọ tawọn ajinigbe naa ji gbe laipẹ, bi o ṣe ni pe ijọba n sapa wọn lati gba itusilẹ awọn eeyan naa.
DSS lọgun pé àgbébọn fẹ́ kọlu iléẹ̀kọ́ l‘Edo, ìjọba ti iléẹ̀kọ́ mẹ́ta pa
Iwe kan lo lu sita lori ayelujara lojiji, eyi ti ikọ alaabo DSS fi sin ileeṣẹ NSCDC ti a mọ si aabo ara ẹni ni aabo ilu ni gberẹ ipakọ, pe awọn afurasi n mura lati kọlu awọn ile ẹkọ l'Edo.
Janmole sọ fún mi kó tó kú nípa ohun tó fẹ́ ṣe pẹ̀lú àbíkẹ́hìn rẹ̀ láìmọ̀ pé ikú ti súnmọ́ - Alfa
BBC News Yorùbá wà níbi àdúrà ọjọ́ kẹjọ gbajúmọ̀ àgbà òṣèré tíátà, olóògbé Fatai Okiki Adeshina Oshin, ti ọpọ eeyan mọ si Janmọlẹ, ohun tí a mú bọ̀ rèé.
Ẹ̀sùn jìbìtì N69m mí-ìn tún wọlé tọ Blessing CEO, yàtọ̀ sí ti 36m tí wọ́n kọ́kọ́ torí rẹ̀ fi pamọ́ sí àhámọ́
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹfa ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko fi aaye oniduuro silẹ fun Blessing to ti wa lahamọ EFCC lati oṣu to kọja, pẹlu miliọnu mẹwaa naira, ṣugbọn ahamọ EFCC lo pada si.
Kí ni òfin sọ nípa wíwo ilé táwọn ajínigbé bá fi ṣe ibùgbé?
BBC News Yoruba kan si amofin Ademola Owolabi lati ṣalaye ohun ti ofin sọ nipa wiwo ile tawọn ajinigbe ba n lo fi ṣe ibugbe.
MURIC, ẹgbẹ́ Mùsùlùmí nàká àìtọ́ síjọba Oyo pé ó ló ìjínigbé Ogbomoso tako Islam, ìjọba sọ ìdí tí kò ṣe ní fèsì sí ẹ̀sùn náà
Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Oyo, Ọmọba Dotun Oyelade, sọ fun BBC Yoruba wi pe lati ọjọ ti wọn ti ji awọn akẹkọọ ati olukọ lọ ni Esinele ati Yawota l’Ogbomoso ni ijọba ti pinnu pe oun ko ni maa ṣe arohunbọhun pẹlu ẹnikankan lori iṣẹlẹ naa.
Amẹ́ríkà àti Iran ń da àdó olóró bo ara wọn léraléra fún ọjọ́ méjì
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti fẹsun kan Iran pe o yin ado oloro ba ọkọ ofurufu hẹlikọpita oun ni ẹgbẹ Strait of Hormuz, to si ṣe ikọlu si Iran pada lati gbẹsan.
Rélùwéè yà kúrò lójú irin, èèyàn mẹ́ta kú
Ileeṣẹ NRC to n ri si ọrọ ọkọ ofurufu ni Naijiria, ṣalaye pe ẹka mẹrin lo ya kuro lara ọkọ oju irin naa.
Èèyàn mẹ́rin míràn ni ajínigbé tún pa ní Mowe, kì í ṣe ṣọ́jà nìkan - Iléeṣẹ́ ológun
Ninu atẹjade ti Ọgagun Idereghi Samuel Akari, Igbakeji ọga to n ri si ikede nileeṣẹ ologun 35 Artillery Brigade, Alamala niluu Abeokuta, fi sita lo ti ṣalaye eyi.
Àṣírí abilékọ̀ tó jí ara rẹ̀ gbé, béèrè ₦50m owó ìtúsílẹ̀ tú, ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nílé ìtura
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, Eno Ikoedem, ni lọjọ kinni oṣu Kẹfa yii ni ọkunrin kan niluu Benin fi to ọlọpaa pe wọn ti ji iyawo oun, Oluchi Ugbowan ẹni ọdun marundinlaadọta gbe lọ.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Ikọ̀ ọmọ ogun Isreali ṣekúpa olórí Hamas, Abu Karim
Ọjọ Aiku, ọjọ keje oṣu Kẹfa ọdun 2026 ni ikọ ologun Israeli sọ eyi di mimọ loju opo X wọn ti wọn ti kede.
'Ẹ̀sìn àbáláyé ló le yọ Nàìjíríà kúrò nínú ìpèníjà ààbò'
Bi awọn araalu ṣe n wa ojutuu si ipenija aabo Naijiria ni awọn ori ade ọrun ilẹkẹ ko dakẹ, ti wọn n fi imọran lede lori ọna ti wọn ro pe o le mu aabo pada silu.
Ẹ lo agbára àwọn alálẹ̀ láti ṣẹ́gun ìgbéṣùmọ̀mí - Ooni
Ninu alaye rẹ, Ooni Ogunwusi sọ pe o di dandan fun awọn ọba alaye kaakiri ilẹ Yoruba lati mu agbara iṣẹdalẹ lo.
Ṣé lóòótọ́ ni pé Sunday Igboho ló ṣe bí wọ́n ṣe gba ìtúsílẹ̀ àbúrò Adelabu àtàwọn ọmọ rẹ̀? Ohun tí a mọ̀ rèé
Alẹ ọjọ Satide, ọjọ kẹfa oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii ni ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria fidi eyi mulẹ, ninu atẹjade ti Alukoro apapọ; DCP Anthony Okon Placid, fi sita l'Abuja.
Mò sunkún lórí àwọn ọmọ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso, mi ò mọ̀ pé tèmi náà yóò ṣẹlẹ̀ sí mi - Iya Adelabu
Kọmisona ọlọpaa Oyo ṣàlàyé pe awọn oṣiṣẹ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti ijọba apapọ, pẹlu àjọṣepo awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ọlọ́pàá nipinlẹ Oyo lọ pawọpọ sisẹ idoola ẹ̀mí náà.
Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìdúnkokò àwọn agbébọn láti ṣèkọlú sí ilé ẹ̀kọ́ ní Eko
Lara awọn ibi ti wọn darukọ ninu awọn fidio naa pe awọn agbebọn ti balẹ si ni ipinlẹ Eko ni agbegbe Lekki ati Ikorodu ati pe awọn ọlọpaa ti nawọ gan awọn kan ninu awọn agbebọn naa.
Ìdí tí ilé ẹjọ́ fi ní ₦110bn tílé aṣòfin àpapọ̀ fi ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, pín fún àjẹmọ́nú wọn, lòdì sófin
Adajọ Yellim Bogoro lo gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ti ajọ ajafẹtọọmọniyan, SERAP pe ẹjọ lori pe ko ba ofin mu bi awọn aṣofin ṣe na owo naa.
Ṣé Adunni Ade onítíátà bímọ fún ọkọ ọlọ́kọ ni, ló ṣe gbé oyún àtọmọ tó bí lọ́dún méjì sẹ́yìn pamọ́? Áláyé rèé
Adunni Ade ṣalaye pe aijẹ kaye mọ nipa oyun atọmọbinrin toun bi ki i ṣe ti pe wọn ko gbọdọ mọ.
Ìgbákejì alága ìjọba ìbílẹ̀ l'Ekiti tí ọlọ́pàá ló jí ara rẹ̀ gbé dèrò àtìmọ́lé
Ogunjọ osu karun ọdun 2026 niroyin kan jade wi pe wọn ti ji arabinrin Ogunleye, igbakeji alaga ijọba ibilẹ ilejemeje gbe lọ nipinlẹ Ekiti.
Èyí lohun tí òfin sọ nípa àwọn tó bá ń gbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ pé jàndùkú wọ ìlú àti ìjìyà tó wà fún un
Awọn ipinlẹ ti awọn eeyan ti gbe iroyin ẹlẹjẹ pe agbesunmọmi wọ ilu ati ohun ti ofin sọ nipa pinpin iroyin ẹlẹjẹ.
Ṣé lóòótọ́ ni ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ kan ti kú sígbèkùn ajínigbé nínú àwọn tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso? Àlàyé rèé
Iroyin naa lo tubọ mu ibanujẹ ati ikayasoke wa, bẹẹ ni o da omi tutu si ọkan ọpọ ọmọ Naijiria.













































































